ÌTUMỌ̀ ÌWÚRE NÍNÚ ÈDÈ YORÙBÁ
Ní òde-òní, bí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn bá gbọ́ ìpèdè Ìwúre lẹ́nu wa, ohun tí wọ́n máa ń rò lọ́kàn máa ń pa mí ní ẹ̀rín. Àwọn tí èrò wọn máa ń pa mí ní ẹ̀rín jù lọ ni àwọn ọ̀dọ́, pàápàá àwọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́sìn Ọmọlẹ́yìn-Jésù àti àwọn tí ń sin ẹ̀sìn Ìsìláàmù nínú àwùjọ wa. Ohun tí ń ṣe àwọn tí a ń wí yìí ni pé, “oògùn ní ń jẹ́ Ìwúre” lójú tiwọn.
Ṣé oògùn ní ń jẹ́ Ìwúre láwùjọ Yorùbá?
Bí ènìyàn bá ní ọpọlọ tí ń ṣe iṣẹ́ dáadáa, ó yẹ kí ó mọ̀ pé Ìwúre kò túmọ̀ sí oògùn nínú èdè Yorùbá. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, bí a bá ń wá ire kan tí ń dùn wá lọ́kàn láti ọ̀dọ̀ Èdùmàrè, a óò fi ẹnu wa wí ire náà fún Èdùmàrè Ọba Aláṣẹ, kí Èdùmàrè lè fi àṣẹ sí ire tí a ń wá náà. Èròǹgbà wa lórí ire tí a ń wá yẹn ni ó máa ń mú wa fi ẹnu wa wí ire náà. Ire wíwí ni Yorùbá ń pè ní ì-wí-ire=ì+wú-ire=ìwúre.
Taste the Goodness: EL Blends All-Natural Cold-Pressed Juices
Ó yẹ kí a túbọ̀ ṣàlàyé nípa ìpèdè Ìwúre tí ìtúpalẹ̀ ajẹmọ́-ìtumọ̀ mọfọ́lọ́jì rẹ̀ ṣì rújú yìí dáadáa nípa títọpinpin orírun rẹ̀ nínú èdè Yorùbá gan-an. Èdè àwọn Yorùbá tí a mọ̀ sí Ìjẹ̀ṣà, Ifẹ̀, Ìjẹ̀bú àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ tí Ìró Fáwẹ́lì [u] máa máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn ní àwọn àyíká kan ni a lè pè ní orírun ìpèdè Ìwúre yìí nínú èdè Yorùbá. Ìdí ni pé, bí a bá ní kí a tẹ̀ lé òfin ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú ìmọ̀-ẹ̀dá-èdè Yorùbá, ohun tí a óò máa pe Ìwúre yìí nínú èdè tí àwọn onímọ̀ Yorùbá ìpìlẹ̀ fi ẹnu kò sí pé kí gbogbo wa máa jùmọ̀ lò yóò jẹ́ Ìwíre dípò Ìwúre.
Ẹ jẹ́ kí a wo ìpèdè náà ní ìbámu pẹ̀lú èdè àwọn ẹ̀yà Yorùbá a-fi-ìró-u-bẹ̀rẹ̀-ọ̀rọ̀ tí a wí yìí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí:
Ì+wí-ùre=Ì+w+ùre=ì+wùre=ì+wúre=ìwúre
Àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀ nípa ẹ̀dá-èdè dáadáa ni ìtúpalẹ̀ tí a ṣe sí òkè yẹn máa tètè yé dáadáa. Ìdí ni pé, ìlànà ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè ni a lò láti ṣe àlàyé rẹ̀ ní ṣókí. Ohun tí a sì ń sọ níbẹ̀ náà kò ní awo kan tí ó ju awo ẹ̀pà lọ. Bí àwọn ìlú tàbí àgbègbè tí a fún ní oríkì a-fi-ìró-u-bẹ̀rẹ̀-ọ̀rọ̀ yẹn bá fẹ́ pe àwọn ọ̀rọ̀ bí:
1.) ilé=ulé
2.) ìdí=ùdí
3.) ìkòkò=ùkòkò
4.) ìsaasùn=ùsaasùn
5.) irun=urun (nǹkan) nínú èdè Ìjẹ̀bú
6.) ilẹ̀=ulẹ̀ (alẹ̀)
7.) ikete=ukete
8.) ìgèdè (Èdè Èkìtì)/ògèdè(Y/A)=ùgèdè
9.) ìgbálẹ̀=ùgbálẹ̀
10.) Ire=Ure
11.) Ìre=Ùre
A kọ àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì tí ó wà ní àpẹẹrẹ “10.)” àti “11.)” yàtọ̀ nínú àpẹẹrẹ tí ó wà lókè wọ̀nyí láti fi júwe wúnrẹ̀n tí àpilẹ̀kọ wa yìí dá lé. Ẹ jẹ́ kí a kíyè sí àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ yìí nípa bí a ti lo ọ̀rọ̀ tí ó wà ní àpẹẹrẹ “10.)” òkè yẹn àti àpẹẹrẹ “11.)” lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìṣẹ̀dá-ọ̀rọ̀:
12.) Ì+wí+ure=ì+w+ure=ì+wure=ìwúre (Iwíre (Y/A))
13.) Ì+wí+ùre=ì+w+ùre=ì+wúre=ìwúre (Iwúre (Y/A))
Lẹ́yìn tí àlàyé nípa ìtumọ̀ ajẹmọ́-ẹ̀dá-èdè tí yé wa lórí ìpèdè Ìwúre yìí, ohun tí ó kàn ní àlàyé ajẹmọ́-ẹ̀sìn ìgbàlódé tí a mọ̀ sí ẹ̀sìn Ọmọlẹ́yìn-Jésù àti ẹ̀sìn Ìsìláàmù. Nínú àwọn ẹ̀sìn méjèèjì, ohun tí wọ́n ń pe Ìwúre ni ó gbayì nínú àwùjọ wa lóde-òní. Ó lójú àwa ọmọ Yorùbá tí a mọ ìtumọ̀ Ìwúre débi tí a óò tilẹ̀ máa fi sọ̀rọ̀ láàrin ara wa.
Bí àwọn Adarí-Ẹ̀sìn Ọmọlẹ́yìn-Jésù tí a mọ̀ sí Pastor bá fẹ́ sọ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n dijú láti wúre ní èdè Yorùbá, èdè Lárúbáwà ni wọn yóò fi sọ ọ́. Ẹ wo àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí:
14.) Ẹ jẹ́ kí a gba àdúrà.
15.) Ẹ gba àdúrà fún Orílẹ̀-Èdè àgbáyé kí ó má ṣe sí ogun àgbáyé ẹlẹ́ẹ̀kẹta.
Nínú àpẹẹrẹ “14.)” òkè yẹn, ọ̀rọ̀ tí a kọ yàtọ̀ ni àdúrà tí ó túmọ̀ sí wúre ní èdè Yorùbá. Ó ṣe é ṣe kí a rí ọmọ Yorùbá tí yóò jiyàn pé ojúlówó èdè Yorùbá ni ìpèdè àdúrà tí ó wà nínú “14.)” àti “15.)” bí a bá bi wọ́n. Ǹjẹ́ èdè Yorùbá ni àdúrà? Èdè Yorùbá kọ́, ti Lárúbáwá ni oo. Kódà, àwọn Adarí-Ẹ̀sìn Ọmọlẹ́yìn-Jésù tí a mọ̀ sí Pastor náà máa ń sọ èdè Lárúbáwá nínú ìjọ wọn. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ ni ìpèdè Ìwúre tí wọ́n ń pè ní àdúrà yìí. Èdè ilẹ̀ Lárúbáwá ni àdúrà jẹ́, bí ó bá wu àwọn Adarí-Ẹ̀sìn Ọmọlẹ́yìn-Jésù tí a mọ̀ sí Pastor láti sọ èdè Yorùbá tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí èdè abínibí rẹ̀ nínú Ilé-Ìjọsìn, kò yẹ kí ó sọ èdè Lárúbáwá tí ń ṣe àdúrà èyí tí ó yẹ kí ó sọ ni ìwúre tí ó jẹ́ ojúlówó èdè Yorùbá.
Ẹ ṣeun ṣeun.
A kú ojúmọ́ oo.
© Ọ̀mọ̀wé ÌṢỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán, láti ìlú Ọ̀tà Àwórì
Discover more from GBETU TV
Subscribe to get the latest posts sent to your email.